Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, lẹyin naa o maa fẹnu fẹ atẹ́gùn túẹ́túẹ́ sinu méjèèjì, o maa wa ka sínú méjèèjì: {Qul Uwal Loohu Ahad}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbi...

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i-: Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, lẹyin naa o maa fẹnu fẹ atẹ́gùn túẹ́túẹ́ sinu méjèèjì, o maa wa ka sínú méjèèjì: {Qul Uwal Loohu Ahad}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹyin naa o maa fi méjèèjì pa ibi ti o ba ṣeé pa ni ara rẹ, o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ ati oju rẹ, ati ẹ̀yà ti iwájú ninu ara rẹ, o maa ṣe bẹ́ẹ̀ ni ẹẹmẹta.
O ni alaafia - Bukhaariy gba a wa

Àlàyé

Nínú ìtọ́sọ́nà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni pe o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, o si maa gbe wọn sókè- gẹgẹ bi ẹni tí n ṣe adua- o maa wa rọra fẹnu fẹ́ atẹ́gùn si i pẹ̀lú itọ́ díẹ̀, o maa ka àwọn suura mẹtẹẹta naa: {Qul Uwal Loohu Ahad} ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq} ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹ́yìn náà ni o maa fi atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pa ibi ti o ba ṣee pa ni ara rẹ; o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ, ati ojú rẹ, ati ẹya iwaju ara rẹ, o maa pààrà rẹ ni ẹẹmẹta.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Fifẹ kika suuratul Ikhlaas ati Qul Ahuuzu kìíní-kejì ṣiwaju oorun, ati fifi wọn fẹnu fẹ atẹgun túẹ́túẹ́, ati fifi wọn pa ohun ti o ba ṣee pa ninu ara rẹ.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ