“Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ”

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: “Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ”.
O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ki a ma maa kirun ni ile, ti yoo fi wa da gẹgẹ bii awọn iboji ti wọn ko kii n kirun nibẹ. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe pipọ ni ijọsin ni ohun ti a fẹ ati kiki irun akigbọrẹ ninu ile.
  2. Irun kiki ko lẹtọọ ni awọn iboji; nitori pe o jẹ ọna kan ninu awọn ọna ti wọn maa n gba lati ṣe ẹbọ ati kikọja aala nipa awọn ti wọn wa nibẹ, yatọ si irun ti a maa n ki si oku lara.
  3. Kikọ kuro nibi kiki irun nibi awọn sàréè fi ẹsẹ rinlẹ lọdọ awọn saabe, nitori idi eyi ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi kọ lati jẹ ki awọn ile da gẹgẹ bii awọn iboji ti wọn ko kii n kirun nibẹ.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ