?Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ Abu Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un».
O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wipe dajudaju ẹni tí o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni alẹ, dajudaju Ọlọhun a to o kuro nibi aburu ati nkan ti ko dáa, wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi didide loru (irun oru), wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi awọn iranti yòókù, wọn tun sọ pe: Dajudaju mejeji ni odiwọn ti o kere ju ti o le to ninu kika Kuraani nibi idide oru (irun oru), wọn si tun sọ nkan ti o yatọ si ìyẹn, ati pe o sunmọ pe gbogbo nkan ti wọn sọ yẹn naa ni o daa ti gbolohun yẹn naa si ko o sinu.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Alaye ọla ti o wa fun awọn aayah igbẹyin Sūratul Bakọra, ti o bẹrẹ lati ibi gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o wi pe: (Āmana rosūlu…) titi de ipari Sūrah naa.
  2. Awọn igbẹyin Sūratul Bakọra maa n ti aidara ati aburu ati èṣù dànù fún ẹni tí o ba n ka a ti o ba ka a ni alẹ.
  3. Oru bẹrẹ pẹlu wiwọ oorun, o si pari pẹlu yiyọ alufajari.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ