“Ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí ó kọ́ Kuraani ti o si tun kọ́ ẹlòmíràn”

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí ó kọ́ Kuraani ti o si tun kọ́ ẹlòmíràn”.
O ni alaafia - Bukhaariy gba a wa

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa pe ẹni ti o ni ọlá ju ninu awọn Mùsùlùmí ti o si tun ga ju ni ipo ni ọdọ Ọlọhun ni: Ẹni ti o ba kọ́ Kuraani, ni kika ati hiha, ati kike e ni pẹlẹpẹlẹ, ati agbọye rẹ, ati itumọ rẹ, ti o tun wa kọ́ ẹlòmíràn ni ohun ti n bẹ lọdọ rẹ ninu imọ Kuraani pẹlu lílò ó.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Àlàyé iyì Kuraani, ati pe oun ni ọ̀rọ̀ ti o loore ju; tori pe ọ̀rọ̀ Ọlọhun ni.
  2. Ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn akẹ́kọ̀ọ́ ni ẹni tí n kọ́ ẹlòmíràn, kii ṣe ẹni tí ó fi mọ lori ara rẹ nìkan.
  3. Kíkọ́ Kuraani, ati kikọ ẹlòmíràn ni Kuraani kó kike e ati awọn ìtumọ̀, ati awọn idajọ sinu.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ