“Wọn maa sọ fun onikuraani pe: Máa kà, máa gòkè, maa ké gẹgẹ bi o ṣe maa n ké e ni aye, dájúdájú ibùgbé rẹ wa nibi igbẹyin aaya ti o n ka”

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Wọn maa sọ fun onikuraani pe: Máa kà, máa gòkè, maa ké gẹgẹ bi o ṣe maa n ké e ni aye, dájúdájú ibùgbé rẹ wa nibi igbẹyin aaya ti o n ka”.
O daa - Abu Daud ni o gba a wa

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé wọn maa sọ fun ẹni ti n ka Kuraani, ti n lo ohun ti o wa ninu rẹ, ti n dunni mọ́ ọn ni kíkà ati híhá, ti o ba ti wọ alujanna- pé: Maa ka Kuraani, ki o si maa gòkè pẹ̀lú ìyẹn nibi awọn ipò alujanna, ki o si maa ke e gẹ́gẹ́ bí o ṣe maa n ke e ni aye pẹ̀lú pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ ati ifarabalẹ; tori pe ibùgbé rẹ n bẹ nibi opin aaya ti o maa kà.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ẹsan maa wa ni ibamu si iṣẹ ni ti odiwọn ati bi iṣẹ ba ṣe rí.
  2. Ṣiṣenilojukokoro lori kika Kuraani, ati mimu ojú tó o dáadáa, ati hiha a, ati ìrònú jinlẹ nipa rẹ, ati lílo ohun ti o wa ninu ẹ.
  3. Alujanna ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpele ati ipò, onikuraani maa dé ipò ti o ga julọ ninu ẹ.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ