Àlàyé
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, ṣalaye pe wọn yoo mu iku wa ni ọjọ Ajinde, gẹgẹ bii irisi akọ agutan ti o ni funfun ati dudu ninu rẹ, Wọn maa pè pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna! Wọn maa garun, wọn maa gbe ori wọn sókè, wọ́n si maa wò, Ó maa sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ mọ èyí? Wọ́n maa sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni, ikú nìyí, gbogbo wọn sì ti rí i, wọ́n sì mọ̀ ọ́n. Lẹ́yìn náà ni olupepe naa maa pe pe: Ẹyin ọmọ ina, wọn maa ga ọrùn wọn, wọn maa gbe ori wọn sókè, wọ́n sì máa wò, Ó maa sọ pé: “Ṣé ẹ mọ èyí? Wọ́n maa sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni, ikú nìyí, gbogbo wọn sì ti rí i, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; Wọn maa du u, lẹyin naa ni olupepe naa maa sọ pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna, ẹ maa wa nibẹ gbere, ko si ikú, ẹyin ọmọ ina, ẹ máa wà nibẹ gbere, ko si ikú. Ki ìyẹn le jẹ alekun idẹra àwọn mumini, ati ìjìyà fun awọn Kèfèrí. Lẹ́yìn náà ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka: {Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́}. Ni ọjọ igbedide, wọn maa ya àwọn ọmọ alujanna ati awọn ọmọ ina si ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn si maa wọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ ba kangun si ti yoo si ṣe gbere nibẹ, Alaburu maa ká abamọ; torí pé ko ṣe dáadáa, ati ẹni tí ó ṣe to kù díẹ̀ kaato; torí ko lékún nibi iṣẹ rere.