Awọn Juu ni awọn ti a binu si, ti awọn Nasara jẹ awọn ẹni anu

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ 'Adiyyu ọmọ Haatim, lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Awọn Juu ni awọn ti a binu si, ti awọn Nasara jẹ awọn ẹni anu".
O ni alaafia - Tirmiziy ni o gba a wa

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju awọn Juu ni ìjọ kan ti Ọlọhun binu si wọn, nitori pe wọn mọ ododo wọn ko si ṣiṣẹ pẹlu rẹ. Ati pe awọn Nasara ni ìjọ ẹni anu; nitori pe wọn ṣe iṣẹ laini imọ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Idapọ laaarin imọ ati iṣẹ jẹ igbala kuro ni oju ọna awọn ti a binu si ati awọn ẹni anu.
  2. Ikilọ kuro ni oju ọna awọn Juu ati Nasara, ati didunnimọ oju ọna taara ti o ṣe pe oun ni Isilaamu.
  3. Olukuluku ninu awọn Juu ati Nasara ni ẹni anu ti a binu si, ṣùgbọ́n eyi ti o jẹ ẹsa ju ninu awọn iroyin awọn Juu ni ibinu, ti eyi ti o jẹ ẹsa ju ninu awọn iroyin awọn Nasara ni anu.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ