Àlàyé
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ka aaya yii: {Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ – àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè}. Inú rẹ ni Ọlọhun ti sọ pé Oun ni O sọ Kuraani kalẹ fun Anọbi Rẹ, eyi ti o ni àwọn aaya ti itumọ wọn ko ruju, ti a si mọ idajọ wọn, àwọn ni ipilẹ tira naa ati ibuṣẹrisi rẹ, àwọn naa ni ibuṣẹrisi nígbà tí a ba yapa, o tun n bẹ ninu rẹ àwọn aaya miiran ti a le fun ni itumọ oríṣiríṣi, ti itumọ wọn maa n daru lójú àwọn èèyàn kan, tàbí ki o maa lero pe atako n bẹ láàrin rẹ ati aaya mìíràn, lẹyin naa ni Ọlọhun wa ṣàlàyé bi àwọn èèyàn ṣe n lo pẹ̀lú àwọn aaya yii, àwọn ti igbunri kuro nibi òdodo n bẹ ninu ọkan wọn maa fi eyi ti ko ruju silẹ, wọn maa wa gba eyi ti o ruju mu, lati fi le da iruju silẹ ati lati le ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọn a si maa yi itumọ rẹ pada si ohun ti o maa ba ifẹ-inu wọn mu, ṣùgbọ́n àwọn ti ẹsẹ wọn rinlẹ ninu imọ maa mọ eyi ti o ruju yii, wọn maa wa da a pada sibi eyi ti ko ruju, wọn si maa gba a gbọ pe ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni o ti wa, kò si rọrùn ki o daru tabi tako ara wọn, ṣùgbọ́n Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè ti o ni alaafia. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fun iya àwọn mumini, Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ti o ba ti ri awọn ti n tẹle eyi ti o ruju, àwọn yẹn ni Ọlọhun sọ ninu ọ̀rọ̀ Rẹ pe: {Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn}, ki ẹ ṣọ́ra fun wọn, ki ẹ si ma tẹti si wọn.