Àlàyé
Arákùnrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati wa fi ẹjọ́ bi àwọn ẹrú rẹ ṣe n hùwà sùn, pe wọn maa n pa irọ́ fun un, wọn si maa n janba rẹ nibi agbafipamọ, wọn si maa n rẹ́ ẹ jẹ nibi ibalopọ, wọn si maa n yapa àṣẹ rẹ, oun naa si maa n bu wọn, o si maa n na wọn lati kọ́ wọn ni ẹ̀kọ́, o wa bi i leere nipa bi ọrọ oun ṣe maa jẹ pẹlu wọn ni Ọjọ́ Àjíǹde? Ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn, tí ìyà ti o fi jẹ wọn ba jẹ odiwọn ẹṣẹ wọn, o o nii ni ẹsan, o o si nii jẹ ìyà, tí iya ti o fi jẹ wọn ba kere si ẹṣẹ wọn, o maa jẹ alekun ẹsan fun ẹ, ṣùgbọ́n ti iya ti o fi jẹ wọn ba ju ẹṣẹ wọn lọ, wọn maa fi iya jẹ ìwọ naa, wọn si maa gba odiwọn ti o ba le lọ́wọ́ rẹ, wọn si maa fun wọn, ni arákùnrin naa wa rìn jìnnà, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii n sunkún ti o si n pariwo, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fún un pé: Ṣé o o ka tira Ọlọhun ti o sọ pe: {A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò} [Al-Anbiyaa: 47], wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹni kankan ni Ọjọ́ Àjíǹde, àwọn òṣùwọ̀n si maa wa laarin awọn èèyàn pẹ̀lú déédéé, ni arákùnrin naa wa sọ pé: Mo fi Ọlọhun bura irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mi o ri nǹkan kan ti o ni ọla fun èmi ati awọn ju ki a pínyà lọ, mo n fi ọ jẹ́rìí pe gbogbo wọn ti di ọmọlúwàbí nítorí tí Ọlọhun; ni ti ipaya ìṣirò ati ìyà.