Ẹni ti o ba ṣe daadaa ninu Isilaamu wọn ko nii ba a wí nípa nnkan ti o ṣe ni asiko aimọkan, ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu wọn maa ba a wí nípa akọkọ ati igbẹyin”

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ Ibnu Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Arakunrin kan sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, njẹ wọn maa ba wa wí nípa nnkan ti a ṣe ni asiko aimọkan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe daadaa ninu Isilaamu wọn ko nii ba a wí nípa nnkan ti o ṣe ni asiko aimọkan, ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu wọn maa ba a wí nípa akọkọ ati igbẹyin”.
-

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun wiwọ inu Isilaamu, Ati pe dajudaju ẹni ti o ba gba Isilaamu ti Isilaamu rẹ si daa ti o si jẹ olumọkanga olododo; wọn ko nii ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ba ṣe ni asiko aimọkan ninu awọn ẹṣẹ, Ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu pẹ̀lú ki o jẹ ṣọbẹ-ṣelu tabi ki o ṣẹri pada kuro nibi ẹsin rẹ; wọn maa ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ṣe ninu aigbagbọ ati nnkan ti o ṣe ninu Isilaamu.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Àkólékàn awọn Sọhaba- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- ati ipaya wọn ninu nnkan ti o n bẹ fun wọn ninu awọn iṣẹ ti wọn ṣe ni asiko aimọkan.
  2. Isẹnilojukokoro lori iduroṣinṣin lori Isilaamu.
  3. Ọla ti o n bẹ fun wiwọ inu Isilaamu ati pe dajudaju o maa n pa awọn iṣẹ ìṣáájú rẹ́ ni.
  4. Ẹni ti ko ṣe Isilaamu mọ ati ṣọbẹ- ṣelu, wọn yoo ṣe ìṣirò gbogbo iṣẹ́ kọọkan fun un eyi ti o ṣáájú ni asiko aimọkan, ati gbogbo ẹṣẹ kọọkan ti o ṣe ninu Isilaamu.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ