(Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem)

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ Az-Zubair ọmọ Al-Awwaam, o sọ pe: Nigba ti (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) sọkalẹ (At-Takathur: 8), Az-Zubair sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ, dajudaju mejeeji ni dudu meji, eso dabinu ati omi? O sọ pe: “Oun naa ni o maa jẹ”.
O daa - Tirmiziy ni o gba a wa

Àlàyé

Nigba ti ayah sọkalẹ: (Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem) o n túmọ̀ si pe: Wọn maa pada beere lọwọ wọn nipa idupẹ lori nnkan ti Ọlọhun ṣe ni idẹra le wọn lori ninu awọn idẹra, Az-Zubair ọmọ Al-‘Awwam- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, idẹra wo ni wọn maa bi wa leere nipa rẹ? Dajudaju idẹra mejeeji ko kii ṣe nnkan ti wọn le bukaata si ibeere ati pe mejeeji ni eso dabinu ati omi! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: Dajudaju wọn maa bi yin leere nipa idẹra pẹlu isẹsi yii ti ẹ wa nibẹ yìí, nitori pe mejeeji jẹ idẹra nla meji ninu awọn idẹra Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ikanpamọ idupẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori awọn idẹra.
  2. Idẹra, ninu nǹkan ti wọn maa bèèrè nipa rẹ lọ́wọ́ ẹrú ni Ọjọ́ Àjíǹde ni, o kéré ni tabi o pọ.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ