maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn ko nii gba mẹ́wàá miiran titi ti àwọn fi maa mọ imọ ati iṣẹ

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ Abu Abdir-Rahmaan As-Sulamiy- ki Ọlọhun kẹ́ ẹ- o sọ pe: Awọn ti wọn maa n kọ́ wa bi a ṣe maa ka Kuraani ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wa pe àwọn maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn ko nii gba mẹ́wàá miiran titi ti àwọn fi maa mọ imọ ati iṣẹ ti o wa ninu ẹ, wọn sọ pé: A wa kọ́ imọ ati iṣẹ.
O daa - Ahmad ni o gba a wa

Àlàyé

Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu Kuraani, wọn ko si nii bọ si ibòmíràn titi ti wọn fi maa kọ́ imọ ti o wa ninu awọn aaya mẹ́wàá yii ti wọn si maa lò ó, o maa waa ja si pe wọn kọ imọ ati iṣẹ papọ nìyẹn.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti n bẹ fun awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- ati ojúkòkòrò wọn lori kíkọ́ Kuraani.
  2. Kíkọ́ Kuraani maa wáyé pẹ̀lú imọ ati lilo o, kii ṣe pẹ̀lú kika a ati hiha a nìkan.
  3. Ìmọ̀ maa wáyé ṣiwaju ọ̀rọ̀ ati iṣẹ.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ