Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ

Scan the qr code to link to this page

Hadiisi
Àlàyé
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún
Lati ọdọ Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ.
O ni alaafia - Abu Daud ni o gba a wa

Àlàyé

Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- n ṣàlàyé pe àwọn suura Kuraani Alapọn-ọnle maa n sọ̀kalẹ̀ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko si nii mọ ibi ti asopọ rẹ ti ge ati òpin rẹ, titi ti “BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM” fi maa sọ̀kalẹ̀ fun un, igba naa ni o to maa mọ pe suura ti o ṣáájú ti parí, oun si ni ibẹrẹ suura tuntun.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. A maa n fi BASMALAH ṣe opinya laarin awọn suura ni, ayafi láàrin suuratul Anfaal ati suurat At-Taobah.

Àwọn ìsọ̀rí

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ